ORIKI: ORIKI ILU ILARO
![Image](https://blogger.googleusercontent.com/img/b/R29vZ2xl/AVvXsEiZSiE5CGmP16xJTrqBfnNXpItnG7ryDyLkGAJbyFFzUhpZNUtgHcGXwdNrQRtZZvOsyX6NJjqKm1b_yYGMMvCSJZDpcq1hMF0kP5XfNqnoG86w5ABVb135mvMvpA-ZnZt70r6QQkNyqUzr/s320/ILARO.jpg)
Eji ogogo omo iku lodo toti deri'lewa Omo adiye sun won sebi kuku loku, kiwon to lotatan adiye dide oyan fanda Ilaro omo erin lonibu omo efon lo nona Omo pakan lakan leyin jijo awo ni gbori ile omo ina tin jo geregere lori omi Ilaro omo aran o sunwon e ko nigbale omo oku eko omo ijagudu akara Ogogo omo e ba oro omo ina esan ogbo jinijinji ama jo’le gerege Ogogo tin yini lokun lapa omo oku dudu ti koya kunran Omo kulodo to tideri’lewa omo kinikan o joye lesa, tobawa joye lesa nko ilesanmi lasan loba yin muwon je. Ogogo lomo agbele jebu, omo yiyo lanyo nile baba tobiyin lomo Ilaro omo ku la ngberi omo kulodo ao ki wan kuloko tan won di apon Otojo kotojo tomo kulodo nbo lati oko egan loba pade omi sonte, egbon mu aburo na mu gbogbo eni tomu sonte lomu rogbo dan