Eko Akete Ile Ogbon Eko Aromi sa legbe legbe Eko aro sese maja Eko akete ilu okun alagbalugbu omi, Ta lo ni elomi l'eko? ebiwon pe talo ni abatabutu baba omikomi, talo laabata buutu baba odo kodo Eko adele ti angere nsare ju eniyan elese meji lo Eni to o ba lo si ilu eko tiko ba gbon, Koda, bo lo si ilu oyinbo ko legbon mo Afefe toni pon wa ni bebe okun ti yin, faaji to ni pan wa ni bebe osa Eko omo osha nio ose, mase kutere, osha n gbobi, kutere n gbori Eyin lomo afinju woja marin gbendeke, obun woja n wapa sio sio Eyo o Aye'le Eyo o, Eyo baba n teyin to n fi golu n sere, eyin oni sanwo onibode, odilee Ti oju o ba ti ehin igbeti, oju o ni t'eko le source: asatiwatiwa